40
Jobu rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀
1 Olúwa dá Jobu lóhùn sí pẹ̀lú, ó sì wí pé,
2 “Ẹni tí ń bá Olódùmarè wíjọ́ yóò ha kọ ní ẹ̀kọ́?
Ẹni tí ń bá Ọlọ́run wí jẹ́ kí ó dáhùn!”
3 Nígbà náà ni Jobu dá Olúwa lóhùn wá ó sì wí pé,
4 “Kíyèsi i, ẹ̀gbin ni èmi—ohun kí ni èmi ó dà?
Èmi ó fi ọwọ́ mi le ẹnu mi.
5 Ẹ̀ẹ̀kan ní mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kì yóò tún sọ mọ́;
lẹ́ẹ̀kejì ni, èmi kò sì le ṣe é mọ́.”
6 Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àyíká wá, ó sì wí pé,
7 “Di àmùrè gírí ní ẹgbẹ́ rẹ bí ọkùnrin,
èmi ó bi ọ léèrè,
kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.
8 “Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán?
Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo.
9 Ìwọ ni apá bí Ọlọ́run
tàbí ìwọ lè fi ohùn sán àrá bí òun?
10 Fi ọláńlá àti ọlá ìtayọ rẹ̀ ṣe ara rẹ ní ọ̀ṣọ́,
tí ó sì fi ògo àti títóbi ọ̀ṣọ́ bo ara ní aṣọ.
11 Mú ìrunú ìbínú rẹ jáde;
kíyèsí gbogbo ìwà ìgbéraga rẹ kí o sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀.
12 Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyàn kí o sì rẹ ẹ sílẹ̀
kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.
13 Sin gbogbo wọn papọ̀ nínú erùpẹ̀,
kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú.
14 Nígbà náà ní èmi ó yìn ọ́ pé,
ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là.
15 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi Behemoti,
tí mo dá pẹ̀lú rẹ,
òun a máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù.
16 Wò o nísinsin yìí, agbára rẹ wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,
àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ.
17 Òun a máa jù ìrù rẹ̀ bí i igi kedari,
iṣan itan rẹ̀ dìjọ pọ̀.
18 Egungun rẹ̀ ní ògùṣọ̀ idẹ,
Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin.
19 Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run;
síbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́.
20 Nítòótọ́ òkè ńlá ńlá ní i mu ohun jíjẹ fún un wá,
níbi tí gbogbo ẹranko igbó máa ṣiré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀.
21 Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótusì,
lábẹ́ eèsún àti ẹrẹ̀.
22 Igi lótusì síji wọn bò o;
igi arọrọ odò yí i káàkiri.
23 Kíyèsi i, odò ńlá sàn jọjọ, òun kò sálọ;
ó wà láìléwu bí ó bá ṣe pé odò Jordani ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀.
24 Ẹnìkan ha lè mú un ní ojú rẹ̀,
tàbí dẹkùn fún tàbí a máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀?