8
Bilidadi
1 Ìgbà náà ni Bilidadi, ará Ṣuhi, sì dáhùn wí pé,
2 “Ìwọ yóò ti máa sọ nǹkan wọ̀nyí pẹ́ tó?
Tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ yóò sì máa bí ẹ̀fúùfù ńlá?
3 Ọlọ́run a ha máa yí ìdájọ́ po bí?
Tàbí Olódùmarè a máa gbé ẹ̀bi fún aláre?
4 Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣẹ̀ sí i,
ó sì gbá wọn kúrò nítorí ìrékọjá wọn.
5 Bí ìwọ bá sì ké pe Ọlọ́run ní àkókò,
tí ìwọ sì gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ sí Olódùmarè.
6 Ìwọ ìbá jẹ́ mímọ, kí ó sì dúró ṣinṣin:
ǹjẹ́ nítòótọ́ nísinsin yìí òun yóò tají fún ọ,
òun a sì sọ ibùjókòó òdodo rẹ di púpọ̀.
7 Ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ ìbá tilẹ̀ kéré si í,
bẹ́ẹ̀ ìgbẹ̀yìn rẹ ìbá pọ̀ sí i gidigidi.
8 “Èmi bẹ̀ ọ́ ǹjẹ́, béèrè lọ́wọ́ àwọn ará ìgbà nì
kí o sì kíyèsi ìwádìí àwọn baba wọn.
9 Nítorí pé ọmọ-àná ni àwa, a kò sì mọ nǹkan,
nítorí pé òjìji ni ọjọ́ wa ni ayé.
10 Àwọn kì yóò wa kọ ọ́, wọn kì yóò sì sọ fún ọ?
Wọn kì yóò sì sọ̀rọ̀ láti inú òye wọn jáde wá?
11 Papirusi ha lè dàgbà láìní ẹrẹ̀
tàbí eèsún ha lè dàgbà láìlómi?
12 Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò ké e lulẹ̀,
ó rọ dànù, ewéko gbogbo mìíràn hù dípò rẹ̀.
13 Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run,
bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn àgàbàgebè yóò di òfo.
14 Àbá ẹni tí a ó kèé kúrò,
àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dàbí ilé aláǹtakùn.
15 Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró,
yóò fi di ara rẹ̀ mú ṣinṣin ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró pẹ́.
16 Ó tutù bí irúgbìn tí a bomirin níwájú oòrùn,
ẹ̀ka rẹ̀ sì yọ jáde nínú ọgbà rẹ̀.
17 Gbòǹgbò rẹ̀ ta yí ebè ká,
ó sì wó ibi òkúta wọ̀n-ọn-nì.
18 Bí ó bá sì pa á run kúrò ní ipò rẹ̀,
nígbà náà ni ipò náà yóò sọ, ‘Èmi kò ri ọ rí!’
19 Kíyèsi i, ayé rẹ̀ gbẹ dànù
àti láti inú ilẹ̀ ní irúgbìn òmíràn yóò hù jáde wá.
20 “Kíyèsi i, Ọlọ́run kì yóò ta ẹni òtítọ́ nù,
bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ran oníwà búburú lọ́wọ́
21 títí yóò fi fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹnu,
àti ètè rẹ pẹ̀lú ìhó ayọ̀,
22 ìtìjú ní a o fi bo àwọn tí ó kórìíra rẹ̀,
àti ibùjókòó ènìyàn búburú kì yóò sí mọ́.”