3
Jesu kọ́ Nikodemu
Jh 7.50; 19.39; Lk 23.13; Jh 7.26.Ọkùnrin kan sì wà nínú àwọn Farisi, tí a ń pè ní Nikodemu, ìjòyè kan láàrín àwọn Júù. Jh 2.11; 7.31; 9.16; Ap 10.38.Òun náà ní ó tọ Jesu wá ní òru, ó sì wí fún un pé, Rabbi, àwa mọ̀ pé olùkọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ìwọ ń ṣe, nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè ṣe iṣẹ́ àmì wọ̀nyí tí ìwọ ń ṣe, bí kò ṣe pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.
Jh 1.13; 1Pt 1.23; Jk 1.18; 1Jh 3.9.Jesu dáhùn ó sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, bí kò ṣe pé a tún ènìyàn bí, òun kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.”
Nikodemu wí fún un pé, a ó ti ṣe lè tún ènìyàn bí nígbà tí ó di àgbàlagbà tan? Ó ha lè wọ inú ìyá rẹ̀ lọ nígbà kejì, kí a sì bí i?
El 36.25-27; Ef 5.26; Tt 3.5.Jesu dáhùn wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, bí kò ṣe pé a fi omi àti Ẹ̀mí bí ènìyàn, òun kò lè wọ ìjọba Ọlọ́run. 1Kọ 15.50.Èyí tí a bí nípa ti ara, ti ara ni; èyí tí a sì bí nípa ti Ẹ̀mí, ti Ẹ̀mí ni. Kí ẹnu kí ó má ṣe yà ọ́, nítorí mo wí fún ọ pé, ‘A kò lè ṣe aláìtún yín bí.’ El 37.9.Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ sí ibi tí ó gbé wù ú, ìwọ sì ń gbọ́ ìró rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ kò mọ ibi tí ó gbé ti wá, àti ibi tí ó gbé ń lọ, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa ti Ẹ̀mí.”
Nikodemu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Nǹkan wọ̀nyí yóò ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?”
10 Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ṣé olùkọ́ni ní Israẹli ni ìwọ ń ṣe, o kò sì mọ nǹkan wọ̀nyí? 11  Jh 8.26; 1.18; 3.32.Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Àwa ń sọ èyí tí àwa mọ̀, a sì ń jẹ́rìí èyí tí àwa ti rí; ẹ̀yin kò sì gba ẹ̀rí wa. 12  Bí mo bá sọ ohun ti ayé yìí fún yín, tí ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbàgbọ́ bí mo bá sọ ohun ti ọ̀run fún yín? 13  Ro 10.6; Ef 4.9.Kò sì ṣí ẹni tí ó gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, Ọmọ Ènìyàn tí ń bẹ ní ọ̀run. 14  Nu 21.9; Jh 8.28; 12.34.Bí Mose sì ti gbé ejò sókè ní aginjù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni a kò le ṣe aláìgbé Ọmọ Ènìyàn sókè pẹ̀lú. 15  Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, kí ó má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó le ní ìyè àìnípẹ̀kun.”
16  Ro 5.8; 8.32; Ef 2.4; 1Jh 4.9-10.“Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. 17  Jh 8.15; 12.47; Lk 19.10; 1Jh 4.14.Nítorí Ọlọ́run kò rán ọmọ rẹ̀ sí ayé láti dá aráyé lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n kí a le ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba aráyé là. 18  Ẹni tí ó bá gbà á gbọ́, a kò ní dá a lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n a ti dá ẹni tí kò gbà á gbọ́ lẹ́jọ́ ná, nítorí tí kò gba orúkọ ọmọ kan ṣoṣo ti Ọlọ́run gbọ́. 19  Jh 1.4; 8.12; Ef 5.11,13.Èyí ni ìdájọ́ náà pé, ìmọ́lẹ̀ wá sí ayé, àwọn ènìyàn sì fẹ́ òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí tí iṣẹ́ wọn burú. 20  Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ó bá hùwà búburú ní ìkórìíra ìmọ́lẹ̀, kì í sì í wá sí ìmọ́lẹ̀, kí a má ṣe bá iṣẹ́ rẹ̀ wí. 21  1Jh 1.6.Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ ní í wá sí ìmọ́lẹ̀, kí iṣẹ́ rẹ̀ kí ó lè fi ara hàn pé a ṣe wọ́n nípa ti Ọlọ́run.”
Ẹ̀rí Johanu nípa Jesu
22  Jh 4.2.Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sí ilẹ̀ Judea; ó sì dúró pẹ̀lú wọn níbẹ̀ ó sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi fún ni. 23 Johanu pẹ̀lú sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi ní Aenoni, ní agbègbè Salimu, nítorí tí omi púpọ̀ wà níbẹ̀, wọ́n sì ń wá, a sì ń tẹ̀ ẹ́ wọn bọ omi. 24  Mk 1.14; 6.17-18.(Nítorí tí a kò tí ì sọ Johanu sínú túbú). 25 Nígbà náà ni iyàn kan wà láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu àti Júù kan nípa ti ìwẹ̀nù. 26  Jh 1.7,28.Wọ́n sì tọ Johanu wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Rabbi, ẹni tí ó ti wà pẹ̀lú rẹ lókè odò Jordani, tí ìwọ ti jẹ́rìí rẹ̀, wò ó, òun tẹ àwọn ènìyàn bọ omi, gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá.”
27  1Kọ 4.7.Johanu dáhùn ó sì wí pé, “Ènìyàn kò le rí nǹkan kan gbà, bí kò ṣe pé a bá ti fi fún ún láti ọ̀run wá. 28  Jh 1.20,23.Ẹ̀yin fúnra yín jẹ́rìí mi pé mo wí pé, ‘Èmi kì í ṣe Kristi náà, ṣùgbọ́n pé a rán mi síwájú rẹ̀.’ 29  Mk 2.19-20; Mt 25.1; Jh 15.11.Ẹni tí ó bá ni ìyàwó ni ọkọ ìyàwó; ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó tí ó dúró tí ó sì ń gbóhùn rẹ̀, ó ń yọ̀ gidigidi nítorí ohùn ọkọ ìyàwó; nítorí náà ayọ̀ mi yí di kíkún. 30 Òun kò lè ṣàì máa pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n èmi kò lè ṣàìmá rẹlẹ̀.
31  Jh 3.13; 8.23; 1Jh 4.5.“Ẹni tí ó ti òkè wá ju gbogbo ènìyàn lọ; ẹni tí ó ti ayé wá ti ayé ni, a sì máa sọ ohun ti ayé. Ẹni tí ó ti ọ̀run wá ju gbogbo ènìyàn lọ. 32  Jh 3.11.Ohun tí ó ti rí tí ó sì ti gbọ́ èyí náà sì ni òun ń jẹ́rìí rẹ̀; kò sì sí ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀. 33 Ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀ fi èdìdì dì í pé, olóòtítọ́ ni Ọlọ́run. 34 Nítorí ẹni tí Ọlọ́run ti rán ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí tí Ọlọ́run fi Ẹ̀mí fún un láìsí gbèdéke. 35 Baba fẹ́ Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo lé e lọ́wọ́. 36  Jh 3.16; 5.24.Ẹni tí ó bá gba Ọmọ gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun, ẹni tí kò bá sì gba Ọmọ gbọ́, kì yóò rí ìyè, nítorí ìbínú Ọlọ́run ń bẹ lórí rẹ̀.”

3:1 Jh 7.50; 19.39; Lk 23.13; Jh 7.26.

3:2 Jh 2.11; 7.31; 9.16; Ap 10.38.

3:3 Jh 1.13; 1Pt 1.23; Jk 1.18; 1Jh 3.9.

3:5 El 36.25-27; Ef 5.26; Tt 3.5.

3:6 1Kọ 15.50.

3:8 El 37.9.

3:11 Jh 8.26; 1.18; 3.32.

3:13 Ro 10.6; Ef 4.9.

3:14 Nu 21.9; Jh 8.28; 12.34.

3:16 Ro 5.8; 8.32; Ef 2.4; 1Jh 4.9-10.

3:17 Jh 8.15; 12.47; Lk 19.10; 1Jh 4.14.

3:19 Jh 1.4; 8.12; Ef 5.11,13.

3:21 1Jh 1.6.

3:22 Jh 4.2.

3:24 Mk 1.14; 6.17-18.

3:26 Jh 1.7,28.

3:27 1Kọ 4.7.

3:28 Jh 1.20,23.

3:29 Mk 2.19-20; Mt 25.1; Jh 15.11.

3:31 Jh 3.13; 8.23; 1Jh 4.5.

3:32 Jh 3.11.

3:36 Jh 3.16; 5.24.