10
Ìran àwọn ọmọ Noa
1 Èyí ni ìran àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti, tí àwọn náà sì bí ọmọ lẹ́yìn ìkún omi.
Ìran Jafeti
2 Àwọn ọmọ Jafeti ni:
Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi.
3 Àwọn ọmọ Gomeri ni:
Aṣkenasi, Rifati àti Togarma.
4 Àwọn ọmọ Jafani ni:
Eliṣa, Tarṣiṣi, Kittimu, àti Dodanimu. 5 (Láti ọ̀dọ̀ àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ń gbé agbègbè tí omi wà ti tàn ká agbègbè wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, ìdílé wọn ní orílẹ̀-èdè wọn, olúkúlùkù pẹ̀lú èdè tirẹ̀).
Ìran Hamu
6 Àwọn ọmọ Hamu ni:
Kuṣi, Ejibiti, Puti àti Kenaani.
7 Àwọn ọmọ Kuṣi ni:
Seba, Hafila, Sabta, Raama, àti Sabteka.
Àwọn ọmọ Raama ni:
Ṣeba àti Dedani.
8 Kuṣi sì bí Nimrodu, ẹni tí ó di alágbára jagunjagun ní ayé. 9 Ó sì jẹ́ ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa; nítorí náà ni a ṣe ń wí pé, “Bí Nimrodu, ògbójú ọdẹ níwájú Olúwa.” 10 Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni Babeli, Ereki, Akkadi, Kalne, gbogbo wọn wà ní ilẹ̀ Ṣinari. 11 Láti ilẹ̀ náà ni ó ti lọ sí Asiria, níbi tí ó ti tẹ ìlú Ninefe, Rehoboti àti Kala, 12 àti Resini, tí ó wà ní àárín Ninefe àti Kala, tí ó jẹ́ ìlú olókìkí.
13 Ejibiti sì bí
Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Naftuhimu. 14 Patrusimu, Kasluhimu (láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistini ti wá) àti àwọn ará Kaftorimu.
15 Kenaani sì bí Sidoni àkọ́bí rẹ̀,
àti Heti. 16 Àti àwọn ará Jebusi, àti àwọn ará Amori, àti àwọn ará Girgaṣi, 17 àti àwọn ará Hifi, àti àwọn ará Arki, àti àwọn ará Sini, 18 àti àwọn ará Arfadi, àti àwọn ará Semari, àti àwọn ará Hamati.
Lẹ́yìn èyí ni àwọn ẹ̀yà Kenaani tànkálẹ̀. 19 Ààlà ilẹ̀ àwọn ará Kenaani sì dé Sidoni, lọ sí Gerari títí dé Gasa, lọ sí Sodomu, Gomorra, Adma àti Seboimu, títí dé Laṣa.
20 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Hamu, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, àti èdè wọn, ní ìpínlẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn.
Ìran Ṣemu
21 A bí àwọn ọmọ fún Ṣemu tí Jafeti jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin: Ṣemu sì ni baba gbogbo àwọn ọmọ Eberi.
22 Àwọn ọmọ Ṣemu ni:
Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu.
23 Àwọn ọmọ Aramu ni:
Usi, Huli, Geteri àti Meṣeki.
24 Arfakṣadi sì bí Ṣela,
Ṣela sì bí Eberi.
25 Eberi sì bí ọmọ méjì:
ọ̀kan ń jẹ́ Pelegi, nítorí ní ìgbà ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ̀ ya; orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Joktani.
26 Joktani sì bí
Almodadi, Ṣelefi, Hasarmafeti, Jera. 27 Hadoramu, Usali, Dikla, 28 Obali, Abimaeli, Ṣeba. 29 Ofiri, Hafila àti Jobabu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Joktani.
30 Agbègbè ibi tí wọn ń gbé bẹ̀rẹ̀ láti Meṣa títí dé Sefari, ní àwọn ilẹ̀ tó kún fún òkè ní ìlà-oòrùn.
31 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Ṣemu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ní èdè wọn, ní ilẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn.
32 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Noa gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, ní orílẹ̀-èdè wọn. Ní ipasẹ̀ wọn ni àwọn ènìyàn ti tàn ká ilẹ̀ ayé lẹ́yìn ìkún omi.