8
Agbọ̀n èso pípọ́n
Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè fihàn mi: agbọ̀n èso pípọ́n. Ó béèrè pé, “Amosi kí ni ìwọ rí.”
Mo sì dáhùn pé, “Agbọ̀n èso pípọ́n.”
Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, “Àsìkò náà pọ́n tó fún àwọn ènìyàn mi Israẹli; Èmi kì yóò dá wọn sí mọ́.”
Olúwa Olódùmarè wí pé, “Ní ọjọ́ náà, àwọn orin tẹmpili yóò yí padà sí ohùn réré ẹkún. Ọ̀pọ̀, àní ọ̀pọ̀ ara òkú ni yóò wà ni ibi gbogbo! Àní ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́!”
Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ń tẹ aláìní lórí ba,
tí ẹ sì ń sọ tálákà di ilẹ̀.
Tí ẹ ń wí pé,
“Nígbà wo ni oṣù tuntun yóò parí
kí àwa bá à lè ta ọkà
kí ọjọ́ ìsinmi kí ó lè dópin
kí àwa bá à le ta jéró?”
Kí a sì dín ìwọ̀n wa kù
kí a gbéraga lórí iye tí a ó tà á
kí a sì fi òsùwọ̀n èké yàn wọ́n jẹ,
kí àwa lè fi fàdákà ra àwọn tálákà,
kí a sì fi bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì ra aláìní,
kí a sì ta jéró tí a kó mọ́ ilẹ̀.
Olúwa ti fi ìgbéraga Jakọbu búra pé, “Èmi kì yóò gbàgbé ọ̀kan nínú ohun tí wọ́n ṣe.
“Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kì yóò ha wárìrì fún èyí?
Àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ kì yóò ha ṣọ̀fọ̀?
Gbogbo ilẹ̀ yóò ru sókè bí omi Naili,
yóò sì ru ú sókè pátápátá bí ìkún omi
a ó sì tì í jáde, a ó sì tẹ̀ ẹ́ rì gẹ́gẹ́ bí odò Ejibiti.
“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa Olódùmarè wí,
“Èmi yóò mú oòrùn wọ̀ ní ọ̀sán,
Èmi yóò mú kí ayé ṣókùnkùn ní ọ̀sán gangan.
10 Èmí yóò yí àsè ẹ̀sìn yín padà sí ọ̀fọ̀,
gbogbo orin yín ni èmi yóò sọ di ẹkún.
Èmi yóò mú kí gbogbo yín wọ aṣọ ọ̀fọ̀,
kí a sì fá orí yín.
Èmi yóò mú kí ìgbà náà rí bí ìṣọ̀fọ̀ fún ọmọkùnrin
kan ṣoṣo tí a bí àti òpin rẹ̀ bí ọjọ́ kíkorò.
 
11 “Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa Olódùmarè wí,
“nígbà tí èmi yóò rán ìyàn sí ilẹ̀ náà,
kì í ṣe ìyàn oúnjẹ tàbí òǹgbẹ fún omi.
Ṣùgbọ́n ìyàn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.
12 Àwọn ènìyàn yóò rìn kiri láti Òkun dé Òkun
wọn yóò sì máa rìn ká láti gúúsù sí àríwá,
wọn yóò máa wá ọ̀rọ̀ Olúwa
ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí i.
13 “Ní ọjọ́ náà
“àwọn arẹwà wúńdíá àti àwọn alágbára ọ̀dọ́mọkùnrin
yóò dákú fún òǹgbẹ omi.
14 Àwọn tí ó fi ẹ̀ṣẹ̀ Samaria búra,
tí wọ́n sì wí pé, ‘Bí ó ti dájú pé ọlọ́run rẹ ń bẹ láààyè, ìwọ Dani,’
bí ó ti dájú pè ọlọ́run rẹ ń bẹ láààyè, ìwọ Beerṣeba,
wọ́n yóò ṣubú,
wọn kì yóò si tún dìde mọ.”